8
Ọgbọ́n n fi ìpè síta
1 Òw 1.20,21.Ǹjẹ́ ọgbọ́n kò ha ń kígbe síta?
Òye kò ha ń gbé ohùn rẹ sókè?
2 Ní ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà,
ní ìkóríta, ní ó dúró;
3 ní ẹgbẹ́ ibodè tí ó wọ ìlú,
ní ẹnu ibodè ni ó ń kígbe sókè:
4 “Sí i yín ẹ̀yin ènìyàn, ní mo ń kígbe pè;
mo gbé ohun mi sókè sí gbogbo ènìyàn.
5 Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ kọ́gbọ́n;
ẹ̀yin aṣiwèrè, ẹ gba òye.
6 Ẹ gbọ́, nítorí tí èmi ó sọ̀rọ̀ ohun iyebíye;
Èmí ṣí ètè mi láti sọ ohun tí ó tọ́,
7 ẹnu mi ń sọ ohun tí í ṣe òtítọ́,
nítorí ètè mi kórìíra ibi.
8 Gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi ni ó tọ́,
kò sí èyí tí ó jẹ́ ẹ̀tàn tàbí àyídáyidà níbẹ̀.
9 Fún olóye gbogbo rẹ̀ ni ó tọ̀nà;
wọ́n jẹ́ aláìlẹ́gàn fún gbogbo ẹni tí ó ní ìmọ̀.
10 Yan ẹ̀kọ́ mi dípò fàdákà,
ìmọ̀ dípò o wúrà àṣàyàn,
11 nítorí ọgbọ́n ṣe iyebíye jù iyùn lọ,
kò sí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ tí a sì le fiwé e.
12 “Èmi, ọgbọ́n ń gbé pẹ̀lú òye;
mo ní ìmọ̀ àti ọgbọ́n-inú.
13 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìkórìíra ibi
mo kórìíra ìgbéraga àti agídí,
ìwà ibi àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.
14 Ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n tí ó yè kooro jẹ́ tèmi
mo ní òye àti agbára.
15 Nípasẹ̀ mi ni ọba ń ṣàkóso
tí àwọn aláṣẹ sì ń ṣe òfin tí ó dára.
16 Nípasẹ̀ mi àwọn ọmọ-aládé ń ṣàkóso,
àti gbogbo ọlọ́lá tí ń ṣàkóso ilẹ̀ ayé.
17 Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn mi,
àwọn tí ó sì wá mi rí mi.
18 Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wà,
ọrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere.
19 Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ;
ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ.
20 Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo,
ní ojú ọ̀nà òtítọ́,
21 mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mi
mo sì ń mú kí ilé ìṣúra wọn kún.
22 “Èmi ni Olúwa kọ́kọ́ dá nínú iṣẹ́ rẹ̀.
Ṣáájú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́;
23 a ti yàn mí láti ayérayé,
láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kí ayé tó bẹ̀rẹ̀.
24 Nígbà tí kò tí ì sí Òkun, ni a ti bí mi,
nígbà tí kò tí ì sí ìsun tí ó ní omi nínú;
25 kí a tó fi àwọn òkè sí ipò wọn,
ṣáájú àwọn òkè ni a ti bí mi,
26 kí ó tó dá ilẹ̀ ayé tàbí àwọn oko rẹ̀
tàbí èyíkéyìí nínú eruku ayé.
27 Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn,
nígbà tí ó fi òsùwọ̀n àyíká sórí ibú omi,
28 nígbà tí ó ṣẹ̀dá òfúrufú lókè
tí ó sì fi orísun ibú omi sí ipò rẹ̀ láì le è yẹsẹ̀,
29 nígbà tí ó ṣe ààlà fún omi Òkun
kí omi má ba à kọjá ààlà àṣẹ rẹ̀,
àti nígbà tí ó pààlà ìpìlẹ̀ ayé.
30 Nígbà náà èmi ni gbẹ́nàgbẹ́nà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀
mo kún fún inú dídùn lójoojúmọ́,
mo ń yọ̀ nígbà gbogbo níwájú rẹ̀.
31 Mo ń yọ̀ nínú gbogbo àgbáyé tí ó dá
mo sì ní inú dídùn sí àwọn ọmọ ènìyàn.
32 “Nítorí náà báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi,
ìbùkún ni fún àwọn tí ó pa ọ̀nà mi mọ́.
33 Fetí sí ìtọ́sọ́nà mi kí o sì gbọ́n;
má ṣe pa á tì sápá kan.
34 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó fetísílẹ̀ sí mi,
tí ń ṣọ́nà ní ẹnu-ọ̀nà mi lójoojúmọ́,
tí ń dúró ní ẹnu-ọ̀nà mi.
35 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi rí ìyè
ó sì rí ojúrere gbà lọ́dọ̀ Olúwa.
36 Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti rí ń pa ara rẹ̀ lára
gbogbo ẹni tí ó kórìíra mi fẹ́ ikú.”