7
Ìkìlọ̀ nítorí àwọn aṣẹ́wó
Ọmọ mi, pa ọ̀rọ̀ mi mọ́,
sì fi àwọn òfin mi pamọ́ sínú ọkàn rẹ.
Pa òfin mi mọ́, ìwọ yóò sì yè
tọ́jú ẹ̀kọ́ mi bí ẹyinlójú rẹ.
Kọ wọ́n sí ọwọ́ òsì rẹ, má ṣe fi jẹun
kọ wọ́n sí inú wàláà àyà rẹ.
Wí fún ọgbọ́n pé, “Ìwọ ni arábìnrin mi,”
sì pe òye ní ìbátan rẹ.
Wọn yóò pa ó mọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin alágbèrè,
kúrò lọ́wọ́ àjèjì obìnrin àti ọ̀rọ̀ ìtànjẹ rẹ̀.
 
Ní ojú fèrèsé ilé è mi
mo wo ìta láti ojú fèrèsé.
Mo rí i láàrín àwọn aláìmọ̀kan
mo sì kíyèsi láàrín àwọn ọ̀dọ́kùnrin,
ọ̀dọ́ kan tí ó ṣe aláìgbọ́n.
Ó ń lọ ní pópónà ní tòsí i ilé alágbèrè obìnrin náà,
ó ń rìn lọ sí ọ̀nà ilé e rẹ̀.
Ní ìrọ̀lẹ́ bí oòrùn ṣe ń wọ̀,
bí òkùnkùn ṣe ń bo ni lára.
 
10 Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan jáde wá láti pàdé rẹ̀,
ó múra bí panṣágà pẹ̀lú ètè búburú.
11 (Ó jẹ́ aláriwo àti alágídí,
ìdí rẹ̀ kì í jókòó nílé;
12 bí ó ti ń já níhìn-ín ní ó ń já lọ́hùn ún
gbogbo orígun ni ó ti ń ba ní ibùba.)
13 Ó dìímú, ó sì fẹnukò ó ní ẹnu
pẹ̀lú ojú díndín ó wí pé,
 
14 “Mo ní ọrẹ àlàáfíà ní ilé;
lónìí ni mo san ẹ̀jẹ́ mi.
15 Nítorí náà ni n o ṣe jáde wá pàdé è rẹ;
mo wá ọ káàkiri mo sì ti rí ọ!
16 Mo ti tẹ́ ibùsùn mi
pẹ̀lú aṣọ aláràbarà láti ilẹ̀ Ejibiti.
17 Mo ti fi nǹkan olóòórùn dídùn sí ibùsùn mi
bí i òjìá, aloe àti kinamoni.
18 Wá, jẹ́ kí a lo ìfẹ́ papọ̀ ní kíkún títí di àárọ̀;
jẹ́ kí a gbádùn ara wa pẹ̀lú ìfẹ́!
19 Ọkọ ọ̀ mi ò sí nílé;
ó ti lọ sí ìrìnàjò jíjìn.
20 Ó mú owó púpọ̀ lọ́wọ́
kò sì ní darí dé kí ó tó di ọ̀sán.”
 
21 Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ dídùn ó sì í lọ́nà;
ó tàn án jẹ pẹ̀lú ẹnu dídùn.
22 Òun sì tọ̀ ọ́ lọ lẹsẹ̀ kan náà,
bí i màlúù tí ń lọ sí ibi pípa,
tàbí bí àgbọ̀nrín tí ń lọ sí ibi okùn ìso.
23 Títí tí ọ̀kọ̀ fi gún un ní ẹ̀dọ̀,
bí ẹyẹ ṣe ń fẹ́ wọ inú okùn,
láìmọ̀ pé yóò gba ẹ̀mí òun.
 
24 Nítorí náà báyìí ẹ̀yin ọmọ mi, tẹ́tí sí mi
fọkàn sí nǹkan tí mo sọ.
25 Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yà sí ọ̀nà rẹ̀,
tàbí kí ó rìn lọ sí ipa ọ̀nà rẹ̀.
26 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó ti fà lulẹ̀.
Ogunlọ́gọ̀ àwọn alágbára ni ó ti pa.
27 Ilé e rẹ̀ ni ọ̀nà tààrà sí isà òkú,
tí ó lọ tààrà sí àgbàlá ikú.