36
1 Elihu sì tún sọ̀rọ̀ wí pé,
2 “Fún mi láyè díẹ̀ èmi ó sì fihàn ọ́,
nítorí ọ̀rọ̀ sísọ ní ó kún fún Ọlọ́run.
3 Èmi ó mú ìmọ̀ mi ti ọ̀nà jíjìn wá,
èmi ó sì fi òdodo fún Ẹlẹ́dàá mi.
4 Rí i dájú pé ọ̀rọ̀ mi kì yóò ṣèké nítòótọ́;
ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.
5 “Kíyèsi i, Ọlọ́run ni alágbára, òun kò i sì gàn ènìyàn;
ó ní agbára ní ipá àti òye.
6 Òun kì í dá ẹ̀mí ènìyàn búburú sí,
ṣùgbọ́n ó fi òtítọ́ fún àwọn tálákà.
7 Òun kì í mú ojú rẹ̀ kúrò lára olódodo,
ṣùgbọ́n àwọn ọba ni wọ́n wà lórí ìtẹ́;
àní ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé, a sì gbé wọn lékè.
8 Bí ó bá sì dè wọ́n nínú àbà,
tí a sì fi okùn ìpọ́njú dè wọ́n,
9 nígbà náà ni ó ń sọ àwọn ohun tí wọn ti ṣe fún wọn,
wí pé wọ́n ti ṣẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga wọn.
10 Ó sí wọn létí pẹ̀lú sí ọ̀nà ẹ̀kọ́,
ó sì pàṣẹ kí wọn kí ó padà kúrò nínú àìṣedédé.
11 Bí wọ́n bá gbàgbọ́ tí wọ́n sì sìn ín,
wọn ó lo ọjọ́ wọn ní ìrọ̀rùn,
àti ọdún wọn nínú afẹ́.
12 Ṣùgbọ́n, bí wọn kò bá gbàgbọ́,
wọ́n ó ti ọwọ́ idà ṣègbé,
wọ́n á sì kú láìní òye.
13 “Ṣùgbọ́n àwọn àgàbàgebè ní ayé kó ìbínú jọ;
wọn kò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ó bá wọ́n wí.
14 Nígbà náà ni ọkàn wọn yóò kú ní èwe,
ní àárín àwọn ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà.
15 Òun gba òtòṣì nínú ìpọ́njú wọn,
a sì sọ̀rọ̀ sí wọn ní etí nínú ìnira wọn.
16 “Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lúpẹ̀lú ó fa wọn yọ láti inú ìhágágá sí ibi gbòòrò,
sí ibi tí ó ní ààyè tí kò ní wàhálà nínú rẹ̀,
ohun tí a sì gbé kalẹ̀ ní tábìlì rẹ̀ jẹ́ kìkì ọ̀rá oúnjẹ tí ó fẹ́.
17 Ṣùgbọ́n ìwọ kún fún ìdájọ́ àwọn búburú;
ìdájọ́ àti òtítọ́ dì ọ́ mú.
18 Nítorí ìbínú ń bẹ, ṣọ́ra kí òtítọ́ rẹ máa bá a tàn ọ;
láti jẹ́ kí títóbi rẹ mú ọ ṣìnà.
19 Ọrọ̀ rẹ pọ̀ tó, tí wàhálà kì yóò fi dé bá ọ bí?
Tàbí ipa agbára rẹ?
20 Má ṣe ìfẹ́ òru, nígbà tí a ń ké
àwọn orílẹ̀-èdè kúrò ní ipò wọn.
21 Máa ṣọ́ra kí ìwọ ki ó má yí ara rẹ̀ padà sí búburú,
nítorí èyí tí ìwọ rò pé ó dára jù ìpọ́njú lọ.
22 “Kíyèsi i, Ọlọ́run ni gbéga nípa agbára rẹ̀;
ta ni jẹ́ olùkọ́ni bí rẹ̀?
23 Ta ni ó là ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ fún un,
tàbí ta ni ó lè wí pé ìwọ ti ń ṣe àìṣedéédéé?
24 Rántí kí ìwọ kí ó gbé iṣẹ́ rẹ̀ ga,
ti ènìyàn ni yín nínú orin.
25 Olúkúlùkù ènìyàn a máa rí i;
ẹni ikú a máa wò ó ní òkèrè.
26 Kíyèsi i, Ọlọ́run tóbi, àwa kò sì mọ̀ bí ó ti ní òye tó,
bẹ́ẹ̀ ni a kò lè wádìí iye ọdún rẹ̀ rí.
27 “Nítorí pé òun ni ó fa ìkán omi òjò sílẹ̀,
kí wọn kí ó kán bí òjò ní ìkùùkuu rẹ̀,
28 tí àwọsánmọ̀ ń rọ̀ ìrì rẹ̀ sílẹ̀,
tí ó sì fi ń sẹ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ lórí ènìyàn.
29 Pẹ̀lúpẹ̀lú ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè ní ìmọ̀ ìtànká àwọsánmọ̀,
tàbí ariwo àrá láti àgọ́ rẹ̀?
30 Kíyèsi i, ó tan ìmọ́lẹ̀ yí ara rẹ̀ ká
ó sì bo ìsàlẹ̀ òkun mọ́lẹ̀.
31 Nítorí pé nípa wọn ní ń ṣe dájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ènìyàn;
ó sí ń pèsè oúnjẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
32 Ó fi ìmọ́lẹ̀ bo ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì
ó sì rán an sí ẹni olódì.
33 Ariwo àrá rẹ̀ fi ìjì hàn ní;
ọ̀wọ́ ẹran pẹ̀lú wí pé, ó súnmọ́ etílé!