46
Àwọn Ọlọ́run Babeli
1 Beli tẹrí i rẹ̀ ba, Nebo bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀;
àwọn ère wọn ni àwọn ẹranko rù.
Àwọn ère tí wọ́n ń rù káàkiri ti di
àjàgà sí wọn lọ́rùn,
ẹrù fún àwọn tí àárẹ̀ mú.
2 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ wọ́n sì foríbalẹ̀ papọ̀;
wọn kò lè gba ẹrù náà,
àwọn pẹ̀lú ni a kó lọ ní ìgbèkùn.
3 “Tẹ́tí sí mi, ìwọ ilé Jakọbu,
gbogbo ẹ̀yin tí ó ṣẹ́kù nínú ilé Israẹli,
ìwọ tí mo ti gbéró láti ìgbà tí o ti wà nínú oyún,
tí mo sì ti ń pọ̀n láti ìgbà tí a ti bí ọ.
4 Pẹ̀lúpẹ̀lú sí àwọn arúgbó àti ewú orí yín,
Èmi ni ẹni náà, Èmi ni ẹni tí yóò gbé ọ ró.
Èmi ti mọ ọ́, èmi yóò sì gbé ọ;
Èmi yóò dì ọ́ mú èmi ó sì gbà ọ́ sílẹ̀.
5 “Ta ni ìwọ yóò fi mí wé tàbí ta ni èmi yóò bá dọ́gba?
Ta ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé mi
tí àwa yóò jọ fi ara wé ara?
6 Ọ̀pọ̀ da wúrà sílẹ̀ nínú àpò wọn
wọ́n sì wọn fàdákà lórí òsùwọ̀n;
wọ́n bẹ alágbẹ̀dẹ lọ́wẹ̀ láti fi wọ́n ṣe òrìṣà,
wọn sì tẹríba láti sìn ín.
7 Wọ́n gbé e lé èjìká wọn, wọ́n rù wọ́n,
wọ́n sì gbé e sí ààyè rẹ̀ níbẹ̀ ni ó sì dúró sí.
Láti ibẹ̀ náà kò le è paradà.
Bí ènìyàn tilẹ̀ pariwo lé e lórí, òun kò le è dáhùn;
òun kò lè gbà á nínú ìyọnu rẹ̀.
8 “Rántí èyí, fi í sí ọkàn rẹ,
fi sí ọkàn rẹ, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀.
9 Rántí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá, àwọn ti àtijọ́-tijọ́;
Èmi ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlòmíràn;
Èmi ni Ọlọ́run, kò sí ẹlòmíràn bí ì mi.
10 Mo fi òpin hàn láti ìbẹ̀rẹ̀ wá,
láti àtètèkọ́ṣe, ohun tí ó sì ń bọ̀ wá.
Mo wí pé, Ète mi yóò dúró,
àti pé èmi yóò ṣe ohun tí ó wù mí.
11 Láti ìlà-oòrùn wá ni mo ti pe ẹyẹ ajẹran wá;
láti ọ̀nà jíjìn réré, ọkùnrin kan tí yóò mú ète mi ṣẹ.
Ohun tí mo ti sọ, òun ni èmi yóò mú ṣẹ;
èyí tí mo ti gbèrò, òun ni èmi yóò ṣe.
12 Gbọ́ tèmi, ẹ̀yin alágídí ọkàn,
ìwọ tí ó jìnnà sí òdodo.
13 Èmi ń mú òdodo mi bọ̀ nítòsí,
kò tilẹ̀ jìnnà rárá;
àti ìgbàlà mi ni a kì yóò dádúró.
Èmi yóò fún Sioni ní ìgbàlà
ògo mi fún Israẹli.