5
Ìdájọ́ n bọ̀ lórí Israẹli àti Juda
“Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yìn àlùfáà!
Ẹ fetísílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ Israẹli!
Ẹ gbọ́, ẹ̀yìn ilé ọba!
Ìdájọ́ yìí kàn yín.
Ẹ ti jẹ́ ẹ̀bìtì ní Mispa
àwọ̀n ti a nà sílẹ̀ lórí Tabori.
Àwọn ọlọ̀tẹ̀ ti gbilẹ̀ nínú ìpànìyàn
gbogbo wọn ni èmi ó bá wí,
mo mọ ohun gbogbo nípa Efraimu
Israẹli kò sì pamọ́ fún mi
Efraimu, ní báyìí ó ti ṣe àgbèrè
Israẹli sì ti díbàjẹ́.
 
“Ìṣe wọn kò gbà wọ́n láààyè
láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọn.
Ẹ̀mí àgbèrè wà ni ọkàn wọn,
wọn kò sì mọ Olúwa.
Ìgbéraga Israẹli ń jẹ́rìí lé wọn;
àwọn ọmọ Israẹli, àti Efraimu pàápàá kọsẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Juda náà sì kọsẹ̀ pẹ̀lú wọn.
Nígbà tí wọ́n bá lọ pẹ̀lú agbo ẹran
àti ọ̀wọ́ ẹran wọn láti wá Olúwa,
wọn kò ní rí i,
ó ti yọ ara rẹ̀ kúrò láàrín wọn.
Wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Olúwa
wọ́n sì bí àwọn àjèjì ọmọ.
Nísinsin yìí, ọdún oṣù tuntun wọn,
ni yóò pa wọn run pẹ̀lú ìpín wọn.
 
“Fọn fèrè ní Gibeah,
kí ẹ sì fun ìpè ní Rama.
Ẹ pariwo ogun ní Beti-Afeni;
máa wárìrì, ìwọ Benjamini.
Efraimu yóò di ahoro
ní ọjọ́ ìbáwí
láàrín àwọn ẹ̀yà Israẹli,
Mo sọ ohun tí ó dájú.
10 Àwọn olórí Juda dàbí àwọn tí í
máa yí òkúta ààlà kúrò.
Èmi ó tú ìbínú gbígbóná mi lé
wọn lórí bí ìkún omi.
11 A ni Efraimu lára,
a sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ní ìdájọ́,
nítorí pé, ó pinnu láti tẹ̀lé òrìṣà.
12 Mo dàbí kòkòrò aṣọ sí Efraimu,
Mo sì dàbí ìdin ara Juda.
 
13 “Nígbà ti Efraimu ri àìsàn rẹ̀,
tí Juda sì rí ojú egbò rẹ̀
ni Efraimu bá tọ ará Asiria lọ,
ó sì ránṣẹ́ sí ọba ńlá náà fún ìrànlọ́wọ́.
Ṣùgbọ́n kò le è wò ó sàn
bẹ́ẹ̀ ni kò le wo ojú egbò rẹ̀ jinná.
14 Nítorí pé, èmi ó dàbí kìnnìún sí Efraimu,
bí i kìnnìún ńlá sí ilé Juda.
Èmi ó fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ èmi ó sì lọ;
Èmi ó gbé wọn lọ, láìsí ẹni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀.
15 Nígbà náà ni èmi ó padà lọ sí ààyè mi
títí di ìgbà tí wọn ó fi gbà pé àwọn jẹ̀bi
wọn yóò sì wá ojú mi
nínú ìpọ́njú wọn, wọn ó fi ìtara wá mi.”