8
Èdìdì keje àti àwo tùràrí
1 Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì keje, ìdákẹ́rọ́rọ́ sì wà ní ọ̀run níwọ̀n ààbọ̀ wákàtí kan.
2 Mo sì rí àwọn angẹli méje tí wọn dúró níwájú Ọlọ́run; a sì fi ìpè méje fún wọn.
3 Am 9.1; Sm 141.2.Angẹli mìíràn sì wá, ó sì dúró ti pẹpẹ, ó ní àwo tùràrí wúrà kan a sì fi tùràrí púpọ̀ fún un, láti máa fi kún àdúrà gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ lórí pẹpẹ, pẹpẹ wúrà tí ń bẹ níwájú ìtẹ́. 4 Àti èéfín tùràrí náà pẹ̀lú àdúrà àwọn ènìyàn mímọ́ sì gòkè lọ síwájú Ọlọ́run láti ọwọ́ angẹli náà wá. 5 Le 16.12; El 10.2.Angẹli náà sì mú àwo tùràrí náà, ó sì fi iná orí pẹpẹ kùn ún, ó sì dà á sórí ilẹ̀ ayé, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, mọ̀nàmọ́ná sì kọ, àti ilẹ̀-rírì.
Àwọn ìpè
6 Àwọn angẹli méje náà tí wọn ni ìpè méje sì múra láti fún wọn.
7 Ek 9.23-25.Èkínní sì fọn ìpè tirẹ̀, Yìnyín àti iná, tí o dàpọ̀ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀, sì jáde, a sì dà wọ́n sórí ilẹ̀ ayé: ìdámẹ́ta ilẹ̀ ayé si jóná, ìdámẹ́ta àwọn igi sì jóná, àti gbogbo koríko tútù sì jóná.
8 Jr 51.25.Angẹli kejì si fún ìpè tirẹ̀, a sì sọ ohun kan, bí òkè ńlá tí ń jóná, sínú Òkun: ìdámẹ́ta Òkun si di ẹ̀jẹ̀; 9 àti ìdámẹ́ta àwọn ẹ̀dá tí ń bẹ nínú Òkun tí ó ni ẹ̀mí sì kú; àti ìdámẹ́ta àwọn ọkọ̀ si bàjẹ́.
10 Isa 14.12.Angẹli kẹta sì fún ìpè tirẹ̀, ìràwọ̀ ńlá kan tí ń jó bí fìtílà sì bọ́ láti ọ̀run wá, ó sì bọ́ sórí ìdámẹ́ta àwọn odò ṣíṣàn, àti sórí àwọn orísun omi. 11 A sì ń pe orúkọ ìràwọ̀ náà ní Iwọ, ìdámẹ́ta àwọn omi sì di iwọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì tí ipa àwọn omi náà kú, nítorí tí a sọ wọn di kíkorò.
12 Angẹli kẹrin sì fún ìpè tirẹ̀, a sì kọlu ìdámẹ́ta oòrùn, àti ìdámẹ́ta òṣùpá, àti ìdámẹ́ta àwọn ìràwọ̀, ki ìdámẹ́ta wọn lè ṣókùnkùn, kí ọjọ́ má ṣe mọ́lẹ̀ fún ìdámẹ́ta rẹ̀, àti òru bákan náà.
13 Mo sì wò, mo sì gbọ́ idì kan tí ń fò ni àárín ọ̀run, ó ń wí lóhùn rara pé, “Ègbé, ègbé, fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé nítorí ohun ìpè ìyókù tí àwọn angẹli mẹ́ta tí ń bọ̀ wá yóò fún!”