Saamu 41
Fún adarí orin. Saamu Dafidi.
1 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ń ro ti aláìní:
Olúwa yóò gbà á ní ìgbà ìpọ́njú.
2 Olúwa yóò dáàbò bò ó yóò sì pa ọkàn rẹ̀ mọ́:
yóò bùkún fún un ní orí ilẹ̀
kò sì ní fi sílẹ̀ fún ìfẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.
3 Olúwa yóò gbà á lórí àkéte àìsàn rẹ̀
yóò sì mú un padà bọ̀ sípò kúrò nínú àìsàn rẹ̀.
4 Ní ti èmi, mo wí pé “Olúwa, ṣàánú fún mi;
wò mí sàn, nítorí pé mo ti ṣẹ̀ sí ọ”.
5 Àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi nínú àrankàn, pé,
“Nígbà wo ni yóò kú, ti orúkọ rẹ̀ yóò sì run?”
6 Nígbàkígbà tí ẹnìkan bá wá wò mí,
wọn ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, nígbà tí àyà rẹ̀ bá kó ẹ̀ṣẹ̀ jọ sí ara rẹ̀;
nígbà tí ó bá jáde lọ yóò sì máa tàn án kálẹ̀.
7 Àwọn ọ̀tá mi gbìmọ̀ papọ̀ nípa mi;
èmi ni wọ́n ń gbìmọ̀ ibi sí,
8 wọ́n wí pé, “Ohun búburú ni ó dì mọ́ ọn ṣinṣin
àti ní ibi tí ó dùbúlẹ̀ sí,
kì yóò dìde mọ́.”
9 Jh 13.18.Pàápàá, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé,
ẹni tí ó ń jẹ nínú oúnjẹ mi,
tí gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sókè sí mi.
10 Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa, ṣàánú fún mi;
gbé mi sókè, kí ń ba lè san fún wọn.
11 Èmi mọ̀ pé inú rẹ̀ dùn sí mi,
nítorí ọ̀tá mi kò borí mi.
12 Bí ó ṣe tèmi ni
ìwọ dì mímú nínú ìwà òtítọ́ mi
ìwọ sì gbé mi kalẹ̀ níwájú rẹ títí láé.
13 Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli,
láé àti láéláé.
Àmín àti Àmín.