Saamu 28
Ti Dafidi.
Ìwọ Olúwa,
mo ké pe àpáta mi.
Má ṣe kọ etí dídi sí mi.
Tí ìwọ bá dákẹ́ sí mi,
èmí yóò dàbí àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun.
Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú,
bí mo ṣe ń ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́,
bí mo ṣe gbé àwọn ọwọ́ mi sókè
sí Ibi Mímọ́ rẹ Jùlọ.
 
Má ṣe fà mí lọ pẹ̀lú ènìyàn búburú àti,
pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,
tí ń sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò wọn
ṣùgbọ́n tí ìwà ìkà ń bẹ nínú wọn.
San ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn
àti fún iṣẹ́ ibi wọn;
gba ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn;
kí o sì san ẹ̀san wọn bí ó ti tọ́.
 
Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí,
tàbí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀
òun ó rún wọn wọlẹ̀
kì yóò sì gbé wọn ró mọ́.
 
Alábùkún fún ni Olúwa!
Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
Olúwa ni agbára mi àti asà mi;
nínú rẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀lé; àní, ó sì ràn mí lọ́wọ́.
Ọkàn mi sì gbé sókè fún ayọ̀
àní pẹ̀lú orin mi mo fi ọpẹ́ fún un.
 
Olúwa ni agbára àwọn ènìyàn rẹ̀
òun ni odi ìgbàlà àwọn ẹni àmì òróró rẹ̀.
Ìwọ gba àwọn ènìyàn rẹ là, kí o sì bùkún àwọn ajogún rẹ;
di olùṣọ́-àgùntàn wọn, kí o sì gbé wọn lékè títí ayérayé.