22
Orúkọ rere sàn ju ọrọ̀ lọ
Yíyan orúkọ rere sàn ju púpọ̀ ọrọ̀ lọ,
àti ojúrere dára ju fàdákà àti wúrà lọ.
 
Ọlọ́rọ̀ àti tálákà péjọpọ̀:
Olúwa ni ẹlẹ́dàá gbogbo wọn.
 
Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ti rí ibi tẹ́lẹ̀,
ó ṣé ara rẹ̀ mọ́:
ṣùgbọ́n àwọn òpè tẹ̀síwájú, a sì jẹ wọ́n ní yà.
 
Èrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Olúwa ni ọrọ̀ ọlá, àti ìyè.
 
Ègún àti ìdẹ̀kùn ń bẹ ní ọ̀nà aláyídáyidà:
ẹni tí ó bá pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yóò jìnnà sí wọn.
 
Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀:
nígbà tí ó bá dàgbà, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.
 
Ọlọ́rọ̀ ṣe olórí olùpọ́njú,
ajigbèsè sì ṣe ìránṣẹ́ fún ẹni tí a jẹ ní gbèsè.
 
(Gk): 1Kọ 9.7.Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn ẹ̀ṣẹ̀, yóò ká asán:
ọ̀pá ìbínú rẹ̀ yóò kùnà.
 
Ẹni tí ó ní ojú àánú ni a ó bùkún fún;
nítorí tí ó fi nínú oúnjẹ rẹ̀ fún olùpọ́njú.
 
10 Lé ẹlẹ́gàn sí ìta, ìjà yóò sì jáde;
nítòótọ́ ìjà àti ẹ̀gàn yóò dẹ́kun.
 
11 Ẹni tí ó fẹ́ ìwà funfun ti àyà,
tí ó sì ń sọ̀rọ̀ iyì jáde, ọba yóò ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀.
 
12 Ojú Olúwa pa ìmọ̀ mọ́,
ó sì yí ọ̀rọ̀ olùrékọjá pò.
 
13 Ọ̀lẹ wí pé, “Kìnnìún ń bẹ lóde!
Yóò pa mí ní ìgboro!”
 
14 Ẹnu àwọn àjèjì obìnrin, ihò jíjìn ni;
ẹni tí a ń bínú sí láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá ni yóò ṣubú sínú rẹ̀.
 
15 Àyà ọmọdé ni ìwà wèrè dì sí;
ṣùgbọ́n pàṣán ìtọ́ni ni yóò lé e jìnnà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
 
16 Ẹni tó ń ni tálákà lára láti ní ọrọ̀,
tí ó sì ń ta ọlọ́rọ̀ lọ́rẹ,
yóò di aláìní bí ó ti wù kó rí.
Gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́gbọ́n
17 Dẹtí rẹ sílẹ̀,
kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n,
kí o sì fi àyà rẹ sí ẹ̀kọ́ mi.
18 Nítorí ohun dídùn ni bí ìwọ bá pa wọ́n mọ́ ní inú rẹ;
nígbà tí a sì pèsè wọn tán ní ètè rẹ.
19 Kí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ lè wà ní ti Olúwa,
èmi fihàn ọ́ lónìí, àní fún ọ.
20 Èmi kò ha ti kọ̀wé ohun dáradára
sí ọ ní ti ìmọ̀ràn àti ní ti ẹ̀kọ́,
21 kí ó lè mú ọ mọ ìdájú ọ̀rọ̀ òtítọ́;
kí ìwọ le máa fi ìdáhùn òtítọ́
fún àwọn tí ó rán ọ?
 
22 Má ṣe ja tálákà ní olè, nítorí tí ó jẹ́ tálákà:
bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe ni olùpọ́njú lára ní ibodè,
23 nítorí Olúwa yóò gbèjà wọn,
yóò sì gba ọkàn àwọn tí ń gba tiwọn náà.
 
24 Má ṣe bá oníbìínú ènìyàn ṣe ọ̀rẹ́;
má sì ṣe bá ọkùnrin onínú-fùfù rìn.
25 Kí ìwọ má ba à kọ́ ìwà rẹ̀, ìwọ a sì gba ìkẹ́kùn fún ara rẹ.
 
26 Má ṣe wà nínú àwọn tí ń ṣe ìgbọ̀nwọ́,
tàbí nínú àwọn tí ó dúró fún gbèsè.
27 Bí ìwọ kò bá ní nǹkan tí ìwọ ó fi san,
nítorí kín ni yóò ṣe gba ẹni rẹ kúrò lábẹ́ rẹ?
 
28 Má ṣe yẹ ààlà ilẹ̀ ìgbàanì,
tí àwọn baba rẹ ti pa.
 
29 Ìwọ ha rí ènìyàn tí ó ń fi àìṣe ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ rẹ̀?
Òun yóò dúró níwájú àwọn ọba;
òun kì yóò dúró níwájú àwọn ènìyàn lásán.

22:8 (Gk): 1Kọ 9.7.